Native Bible

1 Chronicles 17:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ó lè di fífi ìdí múlẹ̀ àti kí orúkọ rẹ di gbígbéga títí láé. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin yóò wí pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni Ọlọ́run Israẹli.’ Ilé ìránṣẹ́ rẹ Dafidi sì ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.

1 Chronicles 17:24 in English

1 Chronicles 17:24 · Berean Standard Bible

so that Your name will be established and magnified forever when it is said, ‘The LORD of Hosts, the God of Israel, is God over Israel.’ And may the house of Your servant David be established before You.

Context

22Ìwọ ṣe àwọn ènìyàn rẹ Israẹli ní tìrẹ láéláé ìwọ Olúwa sì ti di Ọlọ́run wọn. 23“Nísinsin yìí, Olúwa, jẹ́ kí ìlérí tí ìwọ ti ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ àti ilé rẹ̀ di fífi ìdí múlẹ̀ títí láé. Ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe ìlérí. 24Kí ó lè di fífi ìdí múlẹ̀ àti kí orúkọ rẹ di gbígbéga títí láé. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin yóò wí pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni Ọlọ́run Israẹli.’ Ilé ìránṣẹ́ rẹ Dafidi sì ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ. 25“Ìwọ, Ọlọ́run mi, ti fihan ìránṣẹ́ rẹ pé, ìwọ yóò kọ́ ilé fún un. Bẹ́ẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ ti ní ìgboyà láti gbàdúrà sí ọ. 26Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run. Ìwọ ti fi ìlérí dídára yìí fún ìránṣẹ́ rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.