Native Bible

1 Chronicles 16:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan.

1 Chronicles 16:3 in English

1 Chronicles 16:3 · Berean Standard Bible

Then he distributed to every man and woman of Israel a loaf of bread, a date cake,* and a raisin cake.

Context

1Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run. 2Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ Olúwa. 3Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan. 4Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Lefi láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 5Asafu ni olóyè, àtẹ̀lé rẹ ni Sekariah, Jehieli, Ṣemiramotu, Asieli, Mattitiah, Eliabu, Benaiah, Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn ni yóò lu ohun èlò orin olókùn àti dùùrù haapu. Asafu ni yóò lu símbálì kíkan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.