Native Bible

1 Chronicles 15:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì fi fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Lefi; ẹ̀yin àti àwọn Lefi ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un.

1 Chronicles 15:12 in English

1 Chronicles 15:12 · Berean Standard Bible

And he said to them, “You are the heads of the Levitical families. You and your relatives must consecrate yourselves so that you may bring the ark of the LORD, the God of Israel, to the place I have prepared for it.

Context

10Méjìléláàádọ́fà nínú àwọn ọmọ Usieli; Amminadabu olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀. 11Dafidi sì ránṣẹ́ pe Sadoku, Abiatari tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Urieli, Asaiah. Joẹli, Ṣemaiah, Elieli àti Amminadabu tí wọ́n jẹ́ Lefi. 12Ó sì fi fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Lefi; ẹ̀yin àti àwọn Lefi ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un. 13Nítorí tí ẹ̀yin ọmọ Lefi kò gbe gòkè wá ní ìgbà àkọ́kọ́ ti Olúwa Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ ko lù wá. Àwa kò sì ṣe ìwádìí lọ́wọ́ rẹ̀ nípa bí a ti ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ́nà tí a là sílẹ̀.” 14Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, Ọlọ́run Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.