Native Bible

1 Chronicles 11:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, “Háà, ẹnìkan yóò ha bu omi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu fún un mu?”

1 Chronicles 11:17 in English

1 Chronicles 11:17 · Berean Standard Bible

David longed for water and said, “Oh, that someone would get me a drink of water from the well near the gate of Bethlehem!”

Context

15Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dafidi wá lọ sí orí àpáta nínú ihò Adullamu, nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Filistini sì dúró ní àfonífojì ní orí òkè Refaimu. 16Ní àsìkò náà Dafidi sì ń bẹ nínú ìlú odi, ẹgbẹ́ ogun àwọn ará Filistini sì ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu. 17Dafidi sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, “Háà, ẹnìkan yóò ha bu omi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu fún un mu?” 18Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Filistini, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu ó sì gbé padà tọ Dafidi wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú Olúwa. 19“Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí èmi ó má ṣe ṣe èyí!” ó wí pé. “Ṣé kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dafidi kò ní mu ú. Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.