Native Bible

1 Chronicles 10:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ará Filistini sí lépa Saulu gidigidi àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ rẹ̀. Jonatani, Abinadabu àti Malikiṣua.

1 Chronicles 10:2 in English

1 Chronicles 10:2 · Berean Standard Bible

The Philistines followed hard after Saul and his sons, and they killed Saul’s sons Jonathan, Abinadab, and Malchishua.

Context

1Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa. 2Àwọn ará Filistini sí lépa Saulu gidigidi àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ rẹ̀. Jonatani, Abinadabu àti Malikiṣua. 3Ogun náà sí gbóná janjan fún Saulu, nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́. 4Saulu sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi.” Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é, bẹ́ẹ̀ ni Saulu mú idà tirẹ̀ ó sì ṣubú lé e.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.